Aláàfin: Àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà leè fakọyọ nínú ìṣèjọba

By | May 26, 2018

127 total views, 3 views today

Soworẹ pẹlu Alaafin n sọrọImage copyright @Sowore2019
Àkọlé àwòrán Aláàfin: ní àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà leè fakọyọ nínú ìṣèjọba

Ninu ilepa rẹ lati dije fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria lọdun 2019, Ọmọyẹle Ṣoworẹ kan si aafin Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi III.

Nigba to n tẹwọ gbaa si afin rẹ, alaafin Ọyọ ni awọn ọdọ lorilẹede Naijiria gbọdọ ji ninu orun wọn ki wọn lati gba iṣakoso iṣejọba .

Image copyright @Sowore2019
Àkọlé àwòrán Ṣòwòrẹ́ gbé ìpolongo ìbò dé ọ̀dọ̀ Aláàfin nínú ìlépa rẹ̀ láti di ààrẹ
Loading...

Iku baba yeye woye pe awọn ọdọ lawọn agbegbe miran lagbaye ni wọn n mu ayipada rere ba orilẹede wọn eleyi to ni awọn ọdọ orilẹede Naijiria pẹlu lee ṣe pẹlu.

Ṣoworẹ wa lara awọn ọdọ orilẹede Naijiria ti wọn n dide bayii lati du ipo aarẹ lọdun 2019.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Leave a Reply

Your email address will not be published.

Loading...