Ìdìbò Ọ̀yọ́: Igbákejì alága kàgbákò ìjàǹbá ọkọ̀

By | May 15, 2018

77 total views, 7 views today

Adéyẹmọ Ọ̀jẹ̀déléImage copyright NAtional Insight
Àkọlé àwòrán Ọjọ́ tó yẹ kó jẹ́ ọjọ́ ẹ̀yẹ fún Adéyẹmọ Ọ̀jẹ̀délé, ló jáde láyé.

Ọ́lọ́run má jẹ́ kí ayọ̀ wa dàpọ̀ mọ́ ìbànújẹ́, à sé àdúrà ńlá, tó yẹ ká tètè máa se àmín sí ni.

Ìdí ni pé ọjọ́ tó yẹ kó jẹ́ ọjọ́ ẹ̀yẹ fún Adéyẹmọ Ọ̀jẹ̀délé ló jáde láyé.

Ológbèé yìí, tíí se igbákejì alága tuntun, ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìrẹ́pọ̀, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí wọn sẹ̀sẹ̀ búra fún lọ́jọ́ Ajé, ló kàgbákò ikú òjijì lásìkò ìjàǹbá ọkọ̀ kan tó wáyé nígbà tó ń kó ẹ̀yẹ padà sí ìlú rẹ̀, Kishi, láti ìlú Ìbàdàn tí wọn ti búra fún-un.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adéyẹmọ Ọ̀jẹ̀délé àti ọ̀kan lára àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ nínú òsèlú, ni wọ́n dìjọ ko àgbákò ikú òjijì náà.

Bákan náà ni àwọn èèyàn méjì míì, tí wọn dìjọ wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Honda tó ko ìjàǹbá yìí, náà fara pa yánna-yànna.

Ayọ́kẹ́lé Honda tí wọn wọ̀ gbé òkìtì, lẹ́yìn tí táyà rẹ̀ fọ́ lórí eré

Loading...

Igbákejì alága tuntun, Adéyẹmọ Ọ̀jẹ̀délé náà sì wà lára àwọn alága àti Igbákejì alága tuntun, tí gómìnà Abíọ́lá Ajímọ̀bi búra fún lọ́jọ́ Ajé.

Abúlé Adáfìlà, tó wà lójú ọ̀nà Ògbómọ̀sọ́ sí Ìgbẹ́tì, lágbègbè Òkè-Ògùn ni ti ko ìjàǹbá náà lásìkò tí wọn ń padà bọ̀ láti ibi ayẹyẹ ìbúra náà.

A gbọ́ pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lé Honda tí wọn wọ̀ náà, ló gbé òkìtì, lẹ́yìn tí táyà rẹ̀ fọ́ lórí eré..

Leave a Reply

Your email address will not be published.

Loading...