L’Ógùn, Ọlọ́pàá mú olùkọ́ mẹ́ta fún síso akẹ́kọ̀ọ́ mọ́gi

By | May 17, 2018

30 total views, 3 views today

Image copyright Naija parrot
Àkọlé àwòrán Awọn olukọ ọhun tun kọlu awọn ọlọpaa meji ti wọn gbiyanju ati dawọn lẹkun iwa ọhun.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti mu awọn alaṣẹ ileekọ kan si ahamọ bayii, lori ẹsun pe wọn gbe awọn akẹkọ kan kọ sori igi, nitori pe wọn pẹ de ileewe.

Okiki kan loju opo ikansira ẹni lori itakun agbaye ni ọjọ iṣẹgun, nigbati iroyin nipa awọn alaṣẹ ileewe aladani kan ni agbegbe kan nipinlẹ Ogun, ti wọn gbe awọn akẹkọ kan to pẹ de ileewe kọ igi, gẹgẹ bii ijiya fun iwa apẹlẹyin wọn.

Haa-hin ni ọrọ ọhun n ṣe ọpọ eeyan ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpa nipinlẹ Ogun sọ wi pe, awọn olukọ ti ọrọ kan titi de ori ẹni to ni ileewe naa, ni wọn ti ko, ti wọn si ti n wi tẹnu wọn niwaju awọn ọlọpa ẹka ọtẹlẹmuyẹ ni ilu Abẹokuta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Media captionỌmọge Campus: Lọla Alao ní ẹbí Aisha kò tọrọ owó

Alukoro fun ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣalaye fun BBC Yoruba pe, eeyan mẹta lo wa ni ahamọ Ọlọpaa lori ọrọ naa.

“Lootọ ni iṣẹlẹ yii waye. Ẹni to ni ileewe aladani yii, Ọga agba ileewe naa pẹlu olukọ kan ti wa lahamọ bayii. Wọn si maa foju ba ile ẹjọ laipẹ.”

Loading...

Kíni ohun tí Kọmíṣọ́nà fétò ẹ̀kọ́ nípínlẹ̀ Ògùn sọ?

Amọṣa ijọba ipinlẹ Ogun ko tii sọ ohunkohun si ọrọ ọhun.

Nigba ti BBC Yoruba kan si Kọmisọna feto ẹkọ nipinlẹ Ogun, Arabinrin Modupẹ Mojota, o ni ọrọ ọhun ṣajeji si ileeṣẹ eto ẹkọ, paapaa julọ pẹlu igbesẹ gbogbo ti ijọba n gbe lati rii pe, amojuto to peye wa fawọn ileẹkọ.

“Awọn oṣiṣẹ wa ti bẹrẹ iwadi lori rẹ nitori laarọ yii lawa naa gbọ nipa rẹ. Mo fẹ kẹẹ mọ pe awọn nkan to yẹ lo n lọ labẹnu, lati mu eto ẹkọ nipinlẹ Ogun wu oju ri. Bi o ti lẹ jẹ wi pe ileewe aladani leyi ti ṣẹlẹ, sibẹ igbesẹ to tọ yoo waye, ni kete ti mo ba ti gba ẹkunrẹrẹ abajade iwadi lori ọrọ naa.”

Bakannaa ni alukoro ileeṣẹ ọlọpa nipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, tun fi idi rẹ mulẹ pe, awọn eeyan ọhun tun kọlu awọn ọlọpaa meji ti wọn gbiyanju ati dawọn lẹkun lori iwa ọhun.

O ni, awọn ọlọpa mejeeji wa lalafia lẹyin ti ọga ọlọpaa fun agọ ọlọpa to wa ni agbegbe naa atawọn ọlọpaa abẹ rẹ, sare kan si ileewe naa lati gba wọn silẹ.

“Awọn ọlọpa mejeeji gbiyanju lati tu awọn akẹkọ naa silẹ nibi ti wọn so wọn kọ, ṣugbọn awọn alaṣẹ ileewe naa rii igbesẹ wọn gẹgẹ bii eyi ti ko tọna, ni wọn ba tun kọ oju si awọn ọlọpaa, ti wọn si lu wọn bi ẹni lu bara, ki o to di wi pe ọga ọlọpaa agbegbe naa de ibẹ lati gbawọn silẹ.”

Leave a Reply

Your email address will not be published.

Loading...