Ọọ̀ni: N kò lòògùn òyìnbó látìgbà tí mo ti dórí ìtẹ́

By | June 14, 2018

41 total views, 3 views today

Ọọni ile ifẹ, Adeyẹye Ogunwusi,Image copyright Facebook/Ooni Of Ife, Oba Enitan Adeyeye Ogunwusi
Àkọlé àwòrán Ọ̀ọ̀ni Ilé Ifẹ̀ tún ṣílẹ̀kùn fáwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ Yoruba láti tẹ̀síwájú nínú ìpèsè

Ọọni ile ifẹ, Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji ti ṣina adehun eto iṣegun ibilẹ laarin awọn oniṣegun ibilẹ lorilẹede Naijiria ati ileeṣẹ iwadi iṣegun ibilẹ kan ni orilẹede Brazil.

Eyi kun ara awọn igbesẹ Ọọni Ogunwusi lẹnu irinajo rẹ si orilẹede Brazil to n lọ lọwọ.

Ibudo iwadi iṣegun tewe-tegbo naa to wa ni Fiocruz-Bairro Manguinh, Rio de Janeiro, ni orilẹede Brazil lo mu iwadi iṣegun ibilẹ fawọn eeyan orilẹede Brazil ati agbaye lọkunkundun, pẹlu oniruuru ọna abayọ iṣegun ibilẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọọni ile ifẹ ni adehun naa yoo ṣina fun awọn onimọ iṣegun ibilẹ nilẹ Yoruba, lati lee tọju awọn alaisan kaakiri orilẹede Naijiria.

“Mo jẹ ọkan lara awọn ẹri ijafafa iṣegun ilẹ Yoruba paapaa lati igba ti mo ti gun ori itẹ mi o lo ogun oyinbo rara.”

Loading...

“Ọlọrun fun wa ni ewe ati egbo fun eniyan lati mojuto ilera wa. Gbogbo awọn iṣẹda Eledumare lo ni oriṣa ti Eledumare fi si akoso wọn.”

Ọọni Ogunwusi ni, ko tọna lati maa dẹyẹsi imọ iṣegun ati ẹsin gbogbo to wa lati ilẹ Afirika.

Ọọni ni bi gbogbo agbaye ba lee tete tẹwọ gba eto iwosan ibilẹ, yoo ṣe ọpọ iranwọ fun ọmọ eniyan jake jado agbaye.

Naija Trivia:  Are You A True Nigerian?
By gbenga  /  March 8, 2018

Leave a Reply

Your email address will not be published.

Loading...