Ọwọ́ ṣìnkú ọlọ́pàá tẹ àwọn adigunjalè apanìyàn Ọfa míràn

By | May 21, 2018

135 total views, 3 views today

Awọn adihgunjale Ofa
Àkọlé àwòrán Ojú olè rèé!!!!!!

Ọwọ́ àwọn agbofinro ti tẹ àwọn ọbayejẹ to gbomi lójú àwọn ara Ọfa nipinlẹ Kwara

Awọn ọlọ́pàá ti mu àwọn ole ti won ja ni Ofa ti wọn ṣe ikú pa ọpọlọpọ eniyan.

Awọn ọlọ́pàá fi aworan àwọn olè naa sita ninu ẹrọ ayelujara pẹlu ileri owo milionu marun un naira fun ẹnikẹni to ba kẹfin wọn nigboro tẹlẹ.

Alukoro ọlọ́pàá ni àwọn oninure eniyan ti ń pe wọn fun itọni si awọn ole naa kaakiri ni eyi to ti ń bi èso rere bayii.

Bayii ikọ̀ IRT ti ọga ọlọ́pàá gbe lọ si ipinle Ekiti, Kwara, Oṣun, Oyọ àti Ondo ti mu meji ninu àwon ọgárá ọlọ́ṣà náà.

Awọn olè náà ni:

  • Kunle Ogunlẹyẹ ti àpèjà rẹ je Arrow. O jẹ ọmọ ọdun marundinlogoji. Owọ ọlọ́pàá tẹ̀ẹ́ ni Oró nipinlẹ Kwara lana ti o ti wa.
  • Michael Adikwu ni ẹni keji ti ọwọ́ tẹ̀. O jé ọmọ bibi ijọba ibilẹ Apa nipinlẹ Benue. Wọn ti lee lẹnu iṣk ọlọ́pàá tẹlẹ lọdun 2012 nitori pe o pàdí àpò pẹlu awọn adigunjale ni Kwara ki wọn to fi sẹwọn di ọdun 2015.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Loading...

Atẹjade ti awon ọlọpaa fi sita ni pe Adikwu di ọlọ́ṣà ni kete to jade kuro ni ẹwọn. Osẹ meji sẹyin ni awọn agbofinro IRT tun mu u ni ipinle Kwara.

Gbogbo àwọn afurasi ati awọn ti ọwọ agbofinro ti tẹ̀ ni wọn ti n ran àwon ọlọpaa lọwọ lati mu àwọn to kù wọn.

Image copyright NIGERIA POLICE
Àkọlé àwòrán Awọn afurasí náà gbẹ̀mi ogunlọ́gọ̀ ènìyàn pẹ̀lú ọlọ́pàá mẹsan

Alukoro ọlọpaa ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori idigunjale Ofa.

Àkọlé àwòrán Awọn adigunjalè míràn ti ọwọ́ tún tẹ̀

Leave a Reply

Your email address will not be published.

Loading...