World Cup 2018: Salah yóò kópa nínu ìdíje Russia vs Egypt lọjọ Iṣẹgun

By | June 18, 2018

163 total views, 3 views today

Mojamed SalahImage copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Salah ló gba àmì ẹ̀yẹ̀ ẹlẹ́sẹ̀-ayò tó gbá bọ́ọ̀lù sáwọ̀n jù nínú ìdíje Premier League ní sáà tó kọjá

Ìrètí wà pé Salah yóò gbógo fun Egypt nínú ìdíje Russia 2018.

Awọn ikọ agbabọọlu ilẹ Adulawọ ko tii rọwọ mu daadaa ninu idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ ni Russia yii.

Egypt, Morocco ati Nigeria ti padanu ninu awọn idije akọkọ wọn.

O ku Tunisia ati Senegal bayii ti gbogbo ojú wà lara wọn boya wọn a yọ ikọ Afrika kuro ninu ẹgan yii.

Akọnimọọgba Egypt, Hector Cuper, ti ni Mohamed Salah yoo kopa ninu idije to m bọ lọla laarin Russia to n gbalejo idije World Cup 2018 ati Egypt ti o ba ti yege ninu ayẹwo to fẹ ṣe.

Loading...

O ni: “Ara Salah ti ya, a ni ireti pe yoo gba bọọlu pẹlu ara lile. A kọkọ rò pe ara rẹ ti ya tẹlẹ ni ṣugbọn yoo ṣe ayẹwo aṣepari ṣaaju idije naa pẹlu Russia”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Media captionRussia 2018:Super Eagles ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìdíje tó kọjá

Leave a Reply

Your email address will not be published.

Loading...